IJOBA IBILE NI ILE YORUBA NI AYE ATIJO
LATI OWO
ITOKA AKOONU
IJERISI
IFISORI
IDUPE
ITOKA AKOONU
ORI KIN-NI-NI
IFAARA
ERONGBA
OGBON IWADI
ORI KEJI
ORO NIPA IJOBA IBILE NI ILE YORUBA
BAWO NI ETO IJOBA NAA SE SISE NI AYE ATIJO ATI NI AYE ODE ONI
ORI KETA
IPA TI OBA NKO NI IJOBA IBILE
AWON BABALAWO
AWON OGBONI ATI AWON OBINRIN
AWON ESO
ORI KERIN-IN
AWON TI WON NKAN OBA LOWO LATI RII PE GBOGBO OHUN TI O YE LATI SE NI WON SE AWON ILARI
AWON EYA
IPA TI OBA NKO NINU ETO ISEJOBA ODE ONI
ORI KARUN-UN
AWON ISE ILU
OGUN JIJA ATI OYE JIJE
ERE AWON OBA BALE ATI IJOYE
AWON TI A FI ORO WA LENU WO
AKOJOPO ORUKO IWE TI A YEWO
IWE ITOKASI ATI AWON ABENA IMO
ORI KIN-IN-NI
IFAARA
Ki agbado to de nkan saladiye n je ki oyinbo alawo funfun to de ile wa, alawo dudu ni awon baba nla wa ti n se akoso ijoba ni ibile Yoruba, sugbon nigba ti oyinbo alawo funfun de ni won gbe asa tuntun de nipa fifi awon oba je ni ilana tiwon, won si n gbe esin igbalode ti a mo si kirisiteni ati esin musulumi de eyi ni o faa ti awon omo ode oni ko fi bee kobi ara si oro nipa ijoba ibile ni ile Yoruba.
Awon Yoruba ko fi oro nipa ijoba ibile won sere rara nitori oun gidi ni o je ti o si je oun iwuni lori wipe Yoruba je okan lara awon agbegbe ti o ni ijoba ibile ti o yaranti.
ERONGBA
Erongba sise apinleko yiii nipe ki awa omo ode oni le mo ni kikun nipa ijoba ibile ni ile Yoruba ni aye atijo, nitoripe olaju ti n pa gbogbo nkan da bayii, ko sin ni boju mu ki awa gege bi omo Yoruba male mo tabi so nipa ijoba ni ile Yoruba.
Lara erongba sise apinleko yi nipe ki awon ti o n bo leyin le rii fise ohun elo lati fi se ise ti won, nitoripe nipa opolopo iwe ati opolopo iwadi ni won yoo fi se ise apinleko ti won.
Yoruba bo won ni igba ara la n bura a kii bu sango nigba eerun eyi ni wipe kii apinleko yii le se ayewo asiko ai igba ti a le maa se afihan.
AWON OGBON IWADI
Yoruba bo won ni abeere ona ki sina, idi eyi ni iwadi sise se Pataki ninu ise apinleko nipa sise iwadii ni a fi le mo ohun ti o ni lo lori ohun ti oluwadi fe se iwadi le lori.
A n fi iwadi sise ko oju awon isoro I o ba dojuko wa nipa sise awon ibeere lowo awon ti a mope o mo juwa lo.
Lori apinleko yii opoloppo ogbon ati iwadi ni a ni lai la koja, ki a ba le mo ni kikun nipa ijoba ibile ni ile Yoruba ni aye atijo. A o si fi oro wa awon bii ojogbon , oloye, ati awon ti o dagba I won sin i imo nipa ijoba ibile ni ile Yoruba ni aye atijo , awon wonyi ni a maa fi oro wa lenu wo nipa kiko sile ati nipa gbigba ohun won sile (nipa lilo ero agbonsile).
Lori apinleko yii a o je opolopo akojopo iwe ti a ti owo awon ojogbon ko wo D.O. (1981) awon ibeere ati igbese iwadiii ati ogbon ijinle ai iwadii lenu agba, Ladele T.A.A. (A.Y) (1986) akojopo iwadii ijinle asa Yoruba. Ibadan Macmillan publishers.
ORI KEJI
IJOBA IBILE NI ILE YORUBA
Awon Yoruba gege bii opolopo eya ni ile Africa ti n se ijoba fun ara won kii awon oyinbo alawo funfun to de. Opolopo iwe itan lo so fun wa wipe ilaju ti de si ogunlogo awon eya ti o wan i ile Africa, ki awon oyinbo to mo ohun ti o nje ilaju rara. Ti a ba wo iwe itan ile egypti, sungai, mali ati gana ti n se ijoba fun ara won fun odun pipe ki awon digbolugi ara arebia to de wa doju ijoba won bole. Sugbon kii se itan Africa ni a fe ka, oro nipa ijoba ibile ile Yoruba ni a fe so, enu ko papo nipa ibi ti awon Yoruba ti wa, sugbon apakan ninu iwe itan fi ye ni wipe apa egypti ni awon ti wa. Bi iro, bi ooto ni eyi, a ko le fi owo soya. Sugbon ohun kan ti o se pato ti a le dimu ni wipe o da bi eni pe awon Yoruba ti agbegbe kan wa ti ilosiwaju ti wa ti ohun gbogbo sin i eto leselese. Eleyi fi ara han gbangba nigba ti a bar i wipe gbogbo awon ibi ti Yoruba tedo si ni awon ti ni olori, atele ati ojise ati bee bee lo.
Ti a ba tun woo leekan sii a o rii wipe igba ti awon oyinbo de, paapaa, ti won bere si joba fun wa, ijoba ti a ti n se tele naa ni nwon tele fun opolopo idi, nwon ko le tayo iru ijoba ti a tun se tin ara wa teletele.
Awon oba wa naa ni nwon lo, awon ijoye wa naa si ni isogbe awon oba naa. Eleyi fi ye wa kedere wipe awon Yoruba ko kere rara nipa eto lati se ijoba fun ara won.
BI ETO IJOBA NAA SE SISE SI NI ATIJO
AGBO ILE: Ni agbo ile kookan ni a ti ni enikan ti o dabi kokari ile, oun ni bale ile naa. Ise bale yin ni lati rii wipe ile oun toro, pe o tuba, o si tuse.
Ti gbon-mi-si-omi-o-tokan ba wa laarin eniyan meji ninu ile nigba ti bale ko ba si ni ile, gbogbo won gbodo mu suuru de bale ki o de kin won ro ejo fun un bi oro ti ri, ki o ba won pari re ni eye o soka. Ni igba miran, a maa nri awon ajagila eniyan ti o je wipe bale wa nile lo, ko si nile o, ki awon maa ja wonyii ni, ni tiwon. Bi bale kookan bari iru eniyan bee ni sakani re, ipade ni yoo fa oluwa re lo si.
IDILE
Awon ti a ba bi po ni a n pe ni idile. Baba kan le bi omo meedogun. Bi baba ba ku, ti gbogbo awon omo si dagba ti won si loko ile ti won si aaye otooto, bi o tilejepe awon ko gbe po bayi sibesibe naa, idile ni won je nwon si gbodo maa wa si ipade idile nigba gbogbo. Bi awon agbo ile kookan wonyi ba si bimo, awon omo won nibikibi ti won ba wa, ti di ara idile yii naa niyen nwon si gbodo maa wa si ipade idile bakanna. Ile eni ti o ba dagba ju ni idile yi ni nwon yoo ti maa se ipade ebi won. Eni ti o ba si dagba ju ninu ebi ti n won npe ni eleebi tabi mogaji ni yoo si maa se se alaga idile naa. Ni idile yii arufin ni gbogbo ebi soke-sodo. Bi gbogbo ileto tabi ilu ba pinu wipe ona kan ko tona, ise oniruru eleebi ni lati rii wipe ko si enikan ni gbogbo idile oun ti o rin iru ona naa.
Bi ohunkohun ba sele ni ilu ti ilu si fe pa owo iru ohun naa mo, awon elebijebi ati awon mogaji ni awon maa ranse si lati kilo fun awon idile won yato si gbogbo eleyi, oro wipe a san owo ori deedee lati rii wipe gbogbo omo idile lo san owo ori won. Ise olori ebi ni eyii. Bi idarudapo ba si wa ninu agbo ile kan, ti owo bale agbo ile naa ko kaa, ipade bayi ni a ti npari re. Ohunkohun ti won ba si so ninu ipade naa gbodo te olokuluku lorun, nitori pe nwon yoo gbiyanju gidi lati kan oju abe niko, nwon ko ni footo pamo rara. Bi oyekoye ba wa ti o to si won ni idile yi lati je, inu ipade idile bayi ni nwon yoo tii paa, niwon yoo si dee, titi won yoo fi yan eni ti o ba ye lati yan. Leyin igba ti gbogbo won ba si fi awo sii bayi tan ko si eni ti o gbodo pada lo leyin lati yi ohun ti gbogbo won ti owo si yi.
ADUGBO
Ni adugbo kookan ni a ti ni oloye kan ti yoo maa se olori adugbo naa. Ole sele ki a ni ju oloye kan ni adugbo ikan, sugbon, ni iwon igba ti oga meji kii ti gbe inu oko, enikan soso naa ni yoo je olori adugbo yi. Ohunkuhun ti o ba sele lona odi ni agbo ile kookan jakejado adugbo yi, owo ijoye yi ni a o ti wadi gbogbo eniyan ni yoo si ni ero wipe ijoye naa yo ti mo opolopo nkan nipa ohunkohun ti o ba n sele.
Gbogbo awon ijoye ni nwon maa mba oba jiroro nigba gbogbo, awon si ni oju ati eti oba ni adugbo won.
ILETO
Ilu kekere ni a npe ni ileto. Ni ileto kookan, bale ileto ni olori gbogbo ohun ti o si ti nsele ni ileto yii, owo bale ni a o ti maa beere. Awon bale ileto wonyi naa lagbara pupo, koda ni ileto miran, awon bale gba wipe oba ni awon naa pelu. Ati bale ati mogaji ati ijoye, odo bale ni gbogbo won ti maa fori bale, bale paapaa lo mo bi oun yoo ti toju ilu oun ti ko ni si rogbodiyan ti ko si ni si ogun oun ote. Oun lo mo bi oun se le so ode dero, ti o ba ni ohunkohun ti won ba fe se ni agbegbe, bale yi ni oba agbegbe naa yo ranse si, ohunkohun ti won basi ti so ni ileto ree. Bale ni lati rii wipe gbogbo awon ara ileto oun ni won san owo ori. Ija ti apa bale ko ba si ka ni ileto re, odo oba ni nwon maa nko o lo.
Sugbon ni ode oni ko si ibi ti o n je ileto mo, awon ti won ti ilu keekeekee wa paapaa, ko n fe lode oni ki a so wipe ileto ni won ti wa. Ohun ti a nka wonyii, a nka won gege bi o ti wa latetekose, sugbon kii se bi o ti wan i sinsinyi.
Sungbon ti a ko ba jeki e mo bi o ti ri o seese ki ilaju o de oni ma jeki e moomo.
ILU
Ni gbogbo awon ilu nlanla ni a tin ni oba alaye ni aye atijo awon oba lagbara lopolopo. Ohunkohun ti oba ilu ko ba ti le da se, ile ni yoo gbe idi re ni eyi ti afi nki oba ni “iku ekeji orisa” awa Yoruba gbagbo wipe, leyin orisa, iye ni olorun, awon oba lokan. Idi re niyen ti a fi npe won ni “ Adimula” iyen ni wipe ti a ba di oba mu, ohun naa I baa ti lagbara to, a o la dandan ni. Eni ti oba ba fe ri ni ilu na ni o fe ri, eni ti ko sife ri, ko gbodo duro dola ina yoo moo. Ise oba yii ki se fun ilu yii nikan ni o wa fun gbogbo ileto ti o yii ka. Oba kan soso le ni o ileto mewa si meedogun bale oun nikan. Ise oba si ni lati rii wipe ilu oun toro ati lati rii wipe gbogbo ileto wonyi naa toro minimini. Oba gbodo maa fi awon bale ileto ti o wa labero re, sugbon ti a aba ro wipe awon oba, bale ati ijoye nikan ni o se ilu, iro gbaa ni. Awon ti oo n se ilu po. Sugbon ohun kohun ti won ba ti se, oruko oba ni nwon fi n se.
Ni ilu kookan, gege bi ileto kookan, yato si ijoye, bale tabi oba gidi, o ye ki a tun daruko awon eniyan miran tin won ni ipa oselu.
Sugbon ki a to maa wo eleyi lo, mo fe ki a unbo wo awon oloye wa ni ile Yoruba. Mo fe ki a mo wipe, oye ju oye lo.
Awon oloye kan wa ti o je nkan bi aago mesan si mewa owuro, ni won yoo wolo sile oba. Ti nwon ba ti ki oba lowuro bayi, gbogbo awon ohun bi kolokolo ti o ba w anile, bi ija laarin eniyan meji tabi awon ohun ti o ba ye ni sise laarin ilu, gbogbo re ni nwon maa se patapata kin won to pada sile. Awon ijoye wonyii ni nwon mba oba pero.
Awon ijoye miran tun wa, ti o je wipe ipo ti won tun ga ju ti awon a-boba-pero wonyii orisirisi oruko ni a n pe awon ijoye wonyii ni orisirisi ilu jakejado ile Yoruba. Ni opolopo ilu, iwarafa ni a n pe won. Mo ro wipe oyo nikan ni oruko yi ti yipada ti a ti n pe won ni oyomesi. Awon ijoye wonyi ko n ju mefa si mejo lo n ni ilu kookan. Sugbon nwon lagbara pupopupo.
Ni igba miran, ti awon iwarafa ba pa idi apo po, nwon le si oba ni ipo pada. Oba ti ko fa oju awon ijoye wonyi mora ko fe Alafia fcun ara re. bi oror ba diju tan patapata bi oba ati awon abobapero ati awon iwarafa ba pade ibi ti won ba soro naa si ni abe gee sii ko si omimi kan ti o tun le mi mo.
Sugbon gege bi mo ti so leekan ni gege bi oba tin i agbara to yi ti awon ijoye ajiroba naa si lagbara to, pelu gbogbo agbara ti awon iwarafa ni, awon nikan ko le da ijoba ilu se nitori agidimolaja, awo ile-ife ni won n fi oro ijoba se. awon woni nwon tun mba awon oba, bale ati ijoye se atunse ilu.
AWON ONIFA
Bi oro kan ba sele ni ilu, ti o so ologbon ko ti o si so asiwere ko ohun ti oba maa koko se ni ki o ranse pe ameeku. Ameeku ni olori awon onifa orunmila (orunmila ni o se Pataki julo ninu gbogbo ifa ti a n da ni ile Yoruba) nigba ti ameeku ba de, oba yoo ko, yio si so fun un wipe bayi ni oju won ri to.
IYATO TO WA LAARIN IJOBA IBILE ATIJO ATI ODE ONI
Lara awon iyato ti o wa laarin isejoba ibile aye atijo ati ode oni ni “fifi oba je”
FIFI OBA JE: Leyin osun meta tabi mefa ti oba kan ti waja ni awon afobaje yoo bere sii fi ikunlukun nipa pe to akoko ki won ni oba miiran.
Awon afobaje yii tun ni oruko orisirisi ti a n pe won ni ilu miiran an pe won ni “IWARAFA” “IKORI MESAN” “ABOBAPE” ati bee be lo. Awon afobaje ni yoo pe idile oba ni ilu naa pe ki won fun won ni eniyan won eyi eni ti oba to si lati je, sugbon ife lati gun ori ite oba yoo mu ki opo eniyan naga si jije oba.
Bi opolopo eniyan owo ni idile oba pe won fee je oba, awon afobaje yoo se iwadi si oro naa won yoo losi odo onifa tabi odede omoran lati le yan okan ti o maa tu ilu lara ninu awon ti n dun oye oba.
Ni opolopo ilu akogbodo fi aafin sile lasan idi ni ti a fi n yan iya arugbo kan lati maa iba eto ti o ba le se ni aafin.
Sugbon ni aye ode oni, olaju to de ode oni nipe ti oba ilu kan ba waja se ni awon afobaje ilu yoo ranse si awon idile ti o kan lati maa mura sile wipe idile ti o kan lati maa mura sile wipe idile won ni oba kan, won yoo si ko oruko okunrin ti o ba wa ni ile naa, won yo si mu lo si odo awon afobaje, ni aye atijo eni ti ifa ba ti mu ni yoo je oba ni ilu naa.
Sugbon ni aye ode oni nigba ti won ba ti ko oruko lo si odo awon afobaje. Awon ti o ba lowo ju ni aarin awon ti won ko oruko won yii ni won maa mu, nitoripe olaju ti de eyi lo mu ki won si gba oye ninu iwe je oba laye ode oni. Ni aye ode oni won si tun maa n mu awon ti o ba lowo ninu idile ti oba ba to si nitori won ko fe maa fi otosi je oba laye o de oni mo.
A si tun gbo wipe ni aye atijo a ko gbodo fi aafin sile lasan, eyi si n sele ni aye ode oni, ni aye atijo iya arugbo kan ni won ma fi n se adele, sugbon olaju ti de, ni aye ode oni eto isejoba aye ode oni ni wipe ki won maa yan odomobirin ni opolopo ilu ni ile Yoruba.
ORI KETA
IPA TI OBA N KO NI IJOBA IBILE
Oba yoo si paa lase wipe ki ameeku pelu awon emewa re gbe ife re, ki won si ba oun beere boya opa ilu fe se ni, tabi o tile te lasan. Ameeku yoo si pe awon emewa re jo, won yoo si da ifa lati mo ohun ti o nsele. Leyin igba ti nwon ba ti wadi ohun gbogbo finifini, nwon yoo mu abo wa sodo oba, nwon ko ni fi ohunkohun pamo fun oba ti o ba ni etutu ti o ye ki ilu se ku ilu baa le toro, nwon yoo so fun oba, ti o ba je eleyi ti oba yoo nikan se ni, oba yoo se pelu iyari, ti oba si je eleyi ti gbogbo ilu ati gbogbo agbegbe maa se ni, oba yoo ranse si gbogbo ijoye ati gbogbo awon baale ti o wa ni agbegbe pe ohun ti ifa ni ki won se niyen, Yoo si tee mo gbogbo won leti wipe oro ifa kiise oro agboise. Bi ise naa ba le gidigidi, ibi ti ameeku ti njise yi ni oba yoo ti ranse si awon ti o se sarakisaraki ni ilu ati ni agbegbe kin won wa fi eti won gbooo. Ko si ilu ti o nda duro ni aye atijo lai fi ti ifase, ifa se Pataki pupo ni aye atijo.
AWON BABALAWO
Awon opolopo eniyan maa nro wipe okan naa ni awon onifa ati awon babalawo. Iro nla gbaa ni eyi. A ri onifa ti ko mo oruko ewe kookan ninu igbo, ki a tun maa so wipe yoo ja won se oogun, a si ri babalawo ti ko mo otura yato si orosun, igba yen lo maa mo ejigbe. Sugbon a ri awon babalawo diedie ti o gboogun gbofa. Iwo ni oba o, iwo ni ijoye, iwo ni onifa iwo ni babalawo, nwon jo nse ilu ni. Ti oba tabi baale ba nrii wipe awon abami kan nsele ni ilu, boya lukuluku nja tabi ile gbona, tabi ki ojo ma ro si awon ohun ogbin, ki awon ijoye si ri wipe iyan lo mbo, awon babalawo ni nwon maa ranse pe. Nwon a ranse pe olori awo ki o pe awon eniyan re, ki awon ri ronu si ohun ti nwon yoo se ti gbogbo oro buruku naa nmura ogun latijo, awon babalawo, nipa gidi tin won yoo ko ninu imura yi.
Nitori idi eyi ko se oba baale lati ijoye ti o nse ti ole gbogbo awon babalawo.
AWON OGBONI
Moro wipe a ti ka awon wonyii nibikan ninu iwe yii. Awon eniyan Pataki ti o ba wani ilu ni nwon maa waa ninu egbe yi. Egbe awo gbaa ni, sugbon sibe sibe, opolopo asaro won, ilu ni nwon nfi igbe. Opolopo awon ohun ti oju oba baale ati ijoye ko to, oju awon awo wonyii lo too. Yato si eyi, awo Ibadan, awo egba ati awo ijesa, awo ni gbogbo won jo nse. O seese fun awo wonyii lati fi owo kan ara won ni anfani. Awon oba kii fi oro awon ogboni se yeye rara koda oba paapaaa ni asoju lara awon ogboni ngba miran ewe o le je oro iyann fun oba lati b a awon ogboni pe, ki ilu ba lefi daa si ni.
AWON OBINRIN
E o fiyesi wipe gbogbo awon ti a tin fi enu ba pe okunrin lo poju ninu won, sugbon gege bi gbogbo wa ti mo, okunrin nikan ko lo nse ilu. Tokunrin-tobinrin lo nse ilu, ipa ti obinrin nko ni oro ilu sise, ipa gidi ni. Bi awon obinrin se ni agbara lori okunrin ni aye atijo. Ti abati ni awon obinrin gidi leyin, oro buse. Idi re ni eyi ti opolopo ilu ni ile Yoruba se maa nyan oloye ninu awon obinrin. Ni ilu miran iyalode ni olori awon obinrin. Ni ilu miran, oloo binrin ilu, iyen ni olori obinrin ilu ni oloye ti won maa nyan laarin awon obinrin. Oye yi, oye ilu ni oba ati ijoye ru gbogbo won maa njoko lati yan eni tin won maa fi je oye olori obinrin yi.
Awon oye obinrin miran tun wa ti awon ilu maa nje laarin awon obinrin. Ni awon ilu maa nje laarin awon obinrin. Ni awon ilu miran ni ile Yoruba, bi oba kan bagbese, obinrin ti o je olori awon obinrin yi ni nwon maa nfi se adele oba, oun ni yoo si maa se ijoba titi oba miran yoo fi bo sori oye. Eleyi, yoo fi han wa, ipo ti obinrin ko ni ijoba ni ile Yoruba ni aye ijoun.
AWON ESO
Ni ilu ku lu ti o bade, ti o ba ti mu awon ijoye, ti o simu awon agbaagba ti ko joye awon elemoso ni o kan. Awon wonyii ni awon egbegun, ilu ni aye atijo, tija-tija ni gbogbo ilu nrin.
Ilu ti ko bamu rafun ija tabi ogun, yoo kii. Idi reni eyi ti gbogbo ilu fi maa ni awon olori egbegun, kin won baa le toju awon elemoso ti ilu le pe gbara tin won bamo wipe ogun de.
IPA TI OBA NKO NINU ETO ISEJOBA TODE ONI
Ninu eto isejoba ibile aye atijo, oba ni ipa ti o maa n ko ninu eto ti o bawilu, sugbon ni aye atijo o je oun ti o ye wa wipe awon ti oye ba to si je ni aarin ilu.
Sugbon ipati oba maa n ko ninu eto isejoba ibile Yoruba ni aye ode oni ni wipe oba ni yoo fun awon ti o ba wuu ni oye.
Oba si tun maa n wo bi eniyan ba se gbajumo si ki o to le fun iru eniyan bee ni oye ninu ilu, oba sin i eni ti yoo fun iru eniyan bee ni oye ninu ilu, oba si ni eni ti yoo fun iru eni bee ni oye laarin ilu. Lara ipa ti oba maa n ko ninu eto isejoba Yoruba ni aye ode oni ni ki o nse eto ikowojo lati rii wipe owo wa ninu apo ikowojo lati ri wipe won ni owo fi se oun alumoni si aarin ilu, oba je apase ti o le paa lase fun awon ara ilu wipe itesiwaju ilu ati owo won, yoo si rii wipe ilu ni itesiwaju ilu ati owo won, yoo si rii wipe, ilu ni itesiwaju nipase oba ati awon ara ilu eyi nje ipa kan Pataki ti oba maa n ko ninu eto isejoba tode oni ni eto isejoba ibile aye ode oni.
BI ETO IJOBA SE N SISE NI AYE ODE ONI
Bi eto ijoba se n sise ni aye ode oni ni wipe nigba ti won ba fe yan enikan ti yoo je iludari, tabi bii oba ni aye ode oni won yoo mu enikan ti won ba mo wipe o je eni ti o kawe ti o si je olopolo pipe ti o je wipe koni je ku ijoba ibile won dorikodo ti won si won si mo wipe o lowo lowo oun ni won yoo yan iru eni ti o ba see fi yangan ni awujo bayiii ni wo, yoo yan lati je ko se alakoso tabi oludari ijoba ibile ni aye ode oni.
Eto ijoba ipinle, ijoba ipinle maa n fun awon oba ati awon baale ni ilu kereje kereje laaye lati pase oun ti o wu won, ni aye atijo ko si oun ti o je ase lati odo awon ijoba ipinle, sugbon ni aye ode oni idabobo ti o peye ti wa fun eto isejoba ibile ni ile Yoruba.
Awon alase lati ijoba ipinle ni o nfun awon oba ti won je ni ijoba ibile ni opa ase bii apeere ti oba ilu kan ba sese je olori ijoba ipinle ni yoo fun un ni opa ase, o si tun je oun iyalenu fun wa wipe ni gbogbo agbegbe ijoba ibile ni won ti ni asoju lati odo awon ijoba ipinle ni aye ode oni ti o si je wipe ko si atotonu ti o si le bori ti ijoba ibile aye ode oni mo nipase ase lati odo awon alase ijoba ipinle wa.
ORI KERIN-IN
AWON TI WON N RAN OBA LOWO LATI RII WIPE GBOGBO OHUN TI O YE LATI SE NI WON SE
AWON ILARI
Awon ilari kii se oloye, nwon ko si ni ipin ninu ijoba. Ohun ti a le pe won ni ojise.
Gege bi a ti pe oruko won, nse ni nwon maa nye apakan ori won, ti nwon yoo si fi apa kan re sile laiye nigbakugba ti oba ba fe ranse si won. Ni igba miran, awon ilari wonyi ni oba nran gba isakole lowo awon baale, ti o ba dabi eni pe awon baale ko fe tete san isakole. Se eyin naa si mo wipe ti a ba ran ni se eru, afi je tomo, sugbon ko siti awon ilari ni eyi. Ti a ba ran won nise eru, ise eni ni awon ilari maa n fi je. Eleyi ko jeki o yawa lenu wipe igba pupo ni awon ilari ti da ija sile laarin awon baale agbegbe ati oba won.
AWON EYA
Awon iyawo oba po bi ile oun eni, awon omo oba po bee pelu. Ile oba gboro. Awon eniyan kan lo saa maa toju gbogbo awon ohun ini wonyiii, ninu kin won ma le ba obinrin ta rara fun ara won tabi ki a so won di eya bi eran tabi aja ti a ko fe ki o ba lopo.
Idi ti awon oba fi maa nfe iru awon eniyan bayi ni wipe nwon ko fe awon okunrin ti yoo ma aba iyawo won lopo. Bee ni awon iyawo naa po jantirere ti o je owo enikan ko ka won tan rara. Awon eya wonyii ni, nwon maa roko foba je, awon ni nwon ntoju omo oba, aya oba, ti won sit un maa njise laafin. Ohun kan naa ti oba si nse fun won ni wipe oba nbo won. Ni iwon igba ti ko sisi ohun miran tin won nse ju pe kin won jeun, bokotobokoto ni gbogbo won maa nri.
ORI KARUN-UN
AWON ISE ILU
Gege bi mo ti so saaju, ko si ijoba ti o nfa omi fun eniyan, kosi ijoba ti o nse ona fun eniyan, kosi ijoba ti o se ina fun ilu. Ninu gbogbo oro ile yi, owo ara eni ni a fi ntun aye enise. Looto ko si omi ero, sugbon ona abe-igbo wa. Igba miran, nwon yoo fe tun oja se, tabi kin won tun ile oba se, tabi kin won tun ile imole won se.
Gbogbo eleyi, ise ilu ni. Ti nwon bati fi ise ona odo da ojo fun egbe kan, ninu gbogbo egbe yen jakejado ilu naa, ko si eru ti ko gbodo lo si bi se naa.
Bi oluwa re nku lo bayi, yoo ke ara de ibi ise ilu. Nigba ti o ba de be tin won si rii wipe ara re ko da looto, awon paapaa ni yoo so fun un wipe ki o maa lo sile.
Bi o ba si je pe ile oba ni nwon fe tunse, agaga, gbogbo ilu ni yoo pe sibe. Bi a bari enikan ti o ni ori meji ti o ko lati lo si ibi ise ilu nigbati awon egbe re nlo, awon egbe re gan-an ni yoo se idajo fun un. Nwon le lo si ile re, kin won ro wipe yoo dun-un ju. Nwon yoo si so fun-un wipe ti o ba ni egbaarun, iyeni kobo meedogbon lode oni, ki o wagbe ewure re pada. Bi odaran naa ba ni egbaarun, yoo lo san an, yoo jeki nwon maa gbe ewure lo ta fun eni ti o ba ni owo. Iru idajo bayi ko ni wipe a n lo nso fun oba tabi ijoye kan. Eni ti o ba tapa si ofin egbe re ti tapa si ofin ilu naa niyen.
Nipa sise bayi ise ilu nlo, ilu si wa mimo tonitoni, ona oko, ona odo, ati ona oja naa yoo mo daadaa. Bi ilu baa ni ise kan lati se, ti nwon ba ti le mo egbe ti o ma see, oro ti buse.
OGUN JIJA
Bi ilu kan ba ni ogun lati ba ilu keji ja, orun nyabo ni, ko si eniti ko ni kan. Sugbon kin won to lo si ogun yi, fu n igba pipe, nwon yoo tip e awon onifa, awon ti o nda orunmila agbagba ile ati beebee lo. Gbogbo won yoo ti maa imo won han ni ogun naa ba ye ni jija, ifa yoo ti so fun won, yoo ti mo, bi if aba ni kin won maa lo, sugbon, ifa naa yoo so fun won gbogbo etutu ti nwon yoo se ki nwon baa le bori. Lehin eyi, awon ijoye lehin eyi, awon olori agebgun paapaa, yoose ipade pelu awon elemoso, awon ti won yoo lo koju ogun naa paapaa.
Awon obinrin naa ko kere, awon ni yoo maa boju to ounje wiwa, yala lati rii pe agbado gbingbin, tabi ege gbingbin ko kuna tabi lati rii wipe awon ohun ogbin naa di ounje gidi fun awon omo ogun lati je. Bi ilu kan ba mba ilu keji jagun, oro gbogbo ilu ni ko si eni titi o nku sehin. Iru ogun jija yi wopo ni aye atijo laarin egba ati Ibadan, Ibadan ati ijebu ati ekiti parapo.
OYE JIJE
Ni aye atijo, yato si ode oni, oro wipe a ndu oye ko wopo rara, sugbon kii se wipe kii sele rara.
Bi ipo oloye kan ba si sile ni adugbo kan, ti o si dabi eni pe odudu wo oro eniti o ye ki o jee tabi eni ti ko ni ipin sii, odo oba ni n won nko bo. Oba yoo si ran won leti bi a se nje ni isedale Yoruba, wipe ifa ni a fi waa. Ti o ba dabi eni pe nwon ko fi okan naa ba onifa idile won sise po, oba paapaa le pe onifa ilu ki won si da ifa yi tan, eniti ifa aba wa mu naa ni oba yoo fi owo si. Bi oba ba si ti fi owo sii, bayi, o di ase niyen.
Nipa sise bayi opolopo oro oye tii ba airoju ati aiaye ni oba ati awon igbimo re yoo pa ina re ki dandogo to koja abinuda.
KINI ERE AWON OBA BAALE ATI IJOYE
O ye ki a wadi wipe kini awon oba wa ati baale ati awon ijoye ngba fun gbogbo wahala won lori ijoba ibile. Se eyin naa mo wipe ni aye atijo ko si owo osu ko si ijoba ti o nsan owo osu fun enikan.
Bawo ni awon oba ti n jeun? Ohun kini ti mo fe ki a mo ni wipe opolopo awon ti nwon je oba tabi baale tabi ijoye ni ile Yoruba a-toba-tele ni gbogbo won. Akuro ti ni omi tele ni gbogbo won. Akuro tin i omi tele ki ojo to de ni opolopo won.
Nwon a ti ni de ori jantirere, nwon a si ti ni oko bee pelu. Nigba tin won ba ti de ori oye tan, kii se kini nko je loni. Kini nko mu lola ni wahala, olorun yoo ti kapa iyen fun won.
Bawo ni nwon yoo ti ri owo gbo bukata oye ni ohun ti o le maa ja won laya. Sibe naa, asa wa fi aaye eyi sile.
Lona kinni, ni idile kookan gege bi oloye idile tabi oloye ilu, ile oko idile wa ti o je wipe iwo gege bi oloye ni yoo ma aka obi ibe, iwo ni yoo ma ko eyin nibe, ni aye atijo, obi ti o ma aka ati epo ti o maa ko ninu oko idile yi to lati fi gbo bukata oye.
Lona keji, awon ore ti oloye ngba paapaa to o je. Yala nigba ti nwon ba nje isu tuntun, tabi nwon nse oro idile tabi wipe inu enikan dun, o si fe da wo idunnu fun baale tabi oba ijoye awon nkan ti o nwole fun oloye ko kere.
Lona keta, awon oba, baaale ati awon ijoye ile Yoruba maa ngba isakole, ero awa Yoruba ni wipe oba lo nile. Gbogbo awon ti o ba da oko si ori ile oba ni o gbodo gbe isakole wa nigba ti odun bajo iwo ni koko, isu, epo, ati ohun ti enu nje gbogbo re ni nwon yoo ko wa odo awon ijoye wonyi.
Yato si eyi, awon oba tun ni anfani wipe ohun ti o ba wu won ni won le mu.
Opolopo igba ni awon ilari maa nfi anfani yi kaju fewo ni oja. Bi nwon ba rii eja ti n won si ina igi si iyen di ti oba niyen. Bi o si je isu ni won sina opa si, ti oba niyen. Bi o si je emu bee, bi o si je ewure bee. Bi aye atijo, bi obinrin ba nkoja lo lode, ti o si toka sii wipe o wu oun, obinrin naa di iyawooba niyen. Nibo ni yoo ti maa rin ti o ba sope oun ko fe oba?
Pelupelu, nigba ti awon eniyan ba ko ejo wa sile oba tabi sile bale, awon ijoye kan an nipa wipe awon odaran gbodo sanwo arogbejo, ki won to gbo ohun kohun, lenu awon odaran naa. Ni aye atijo, eyi ko ju nkan bi egbewa si egbewa meji. Nigba ti o ya awon odaran maa nsan to oke kan, kin won to ro ejo, awon owo keekeekee wonyi, ( owo wonyi ko kere ni aye ojo wonyen o) naa ni awon ijoye maa npin tin won yoo je tabi ohun tin won yoo mu. Opolopo won ni owo bi aba bi aba bi erebe, sugbon bi ati sotele, owobowo nile ni ti opolopo ninu won.
AWON TI A FI ORO WA LENU WO
ORUKO | OJO | OJO ORI | ADUGBO |
OLOYE OLUGBENGA IGBALAJOBI | 15/08/16 | AADOTA ODUN | 5 TEMIDIRE STREET, EFON ALAAYE, EKITI STATE |
OLOYE GBEMILEKE OLUSOLA | 22/8/16 | OGORIN ODUN | 35, ILOJA STREET, EFON-ALAAYE, EKITI |
OLOYE BABATUNDE | 08/09/16 | OGOTA ODUN | NO 10 IREAKARI STREET, EFON-ALAAYE EKITI STATE |
OLOYE FALUADE ADEOTI | 15/09/16 | AADORIN ODUN | 7, EREKASAN, STREET, EFON-ALAAYE, EKITI |
AKOJOPO ORUKO AWON IWE TI A YEMO
Akinyemi D.O. (1981) Awon Ibeere Ati Igbese Iwadii Ati Ohun Elo Fun Oro Ibile Ni Ile Yoruba.
Odunjo. J.O. (1974) Ajumoko Oro Ati Ere Ibile Nile Yoruba
Basorun ati balogun S.E. (1995). Apeere igbese ati ilana ise iwadii fun awon oro ibile.
Awolowo O. (1978) Ogbon ijinle ati iwadii lenu agba
Ladele T.A.A. (1986). Akojopo Iwadii Ijinle Asa Yoruba. Ibadan Macmillan pubishers.
The post IJOBA IBILE NI ILE YORUBA NI AYE ATIJO LATI OWO appeared first on TY Computer Institute.
0 Comments