ODUN ARINGIYA NI ILU IKARE AKOKO GEGE BI ERE ONISEODUN ARINGIYA NI ILU IKARE AKOKO GEGE BI ERE ONISE
ITOKA AKOONU
Ifisori
Idupe
ORI KIN – IN – NI
Ifaara
Alaye die nipa odun ibile ni ile Yoruba
Aigbagbo awon Yoruba nipa bibo orisa
Itan isendale ilu Ikare Akoko
Ise ati esin awon ara ilu naa
ORI KEJI
Itan isendale odun aringiya
Bi a se n se odun naa
Awon ohun elo fun odun naa
Odun Aringiya gege bii ere onise
ORI KETA
Igbagbo awon ara ilu nipa sise odun naa
Ipa ti oba maa n ko ninu odun naa
Ipa ti awon ara ilu maa n ko ninu odun naa
ORI KERIN
Awon eewo odun Aringiya
Ayipada ti o ti de ba odun naa
Ero wa nipa odun naa
ORI KARUN – UN
Asokagba
Awon oro ti o ta koko
Awon ti a fi oro wa lenu wo
Awon iwe itokasi

ORI KIN – IN – NI
IFAARA
          Ile aye n yi lo a n to irorun, itura ati iberu Eledaa ni awon omo ode oni ti ju sonu sinu ogbun.  Won ti gbagbe gbogbo asa baba n la won.
          Idi ti a fi yan akori ise yii laayo ni wi pe gbogbo orisa ti awon baba n la wa bo ni aye atijo ni a fe ki awon eniyan mo wipe o ni idi Pataki ti won fi n bo, bii kii o maa mu irorun wo ilu, tabi ki alaafia maa joba ni ilu ati pe ohun idunu ni o je fun wa lati ko iwe apinleko yii fun iwulo ojo iwaju nitori pe awon Yoruba ni igbagbo ti o jinle nipa bibo orisa tabi ki won maa se odun kan jakejado orile ede kaaaro – oojiire.
          Ko si ise kan pato lori akori yii yato si itan ti a gbo lenu awon agbalagba ati ohun ti a ri nigba ti won ba n se odun naa.
Iwe apileko yii dale itan ilu Ikare Akoko, ipo Owa Ale ati Olukare, itan isedale odun Aringiya, igba ti won n se odun naa bi won se n mura sile fun un, bi won se n se odun naa ati ohun elo odun naa tun jeyo.
Ipa ti oba n ko ninu odun yii ati igbagbo awon ara ilu nipa sise odun naa, pelu Pataki odun Aringiya gege bii ere onise ni apileko yii tun kiyesi.
Iwe apileko yii se agbeyewo awon eewo odun Aringiya, ayipada ti o ti deba odun naa, ero wa ni pato ati siso itumo awon oro ti o takoko ati iwe itokasi ni o waye leyin ninu ise yii.
Ona ti a gba lati sise yii ni lati so awon itan ti a ti maa n gbo lenu awon agbalagba ati pe a se akojopo ohun ti a ri lasiko ti won ba n se odun yii.
Eyi fun wa ni aaye lati ni imo to jinle nipa sise odun naa, a si ni igbagbo wipe akitiyan wa lori ise yii yoo mu ilosiwaju ba odun yii.
Ise yii yoo si tun je ona kan Pataki lati polongo asa odun ibile wa kaakiri orile ede Naijiria.
ALAYE DIE NIPA ODUN IBILE NI ILE YORUBA
Se ko kuku si bi ti a kii gbe dana ale, jakejado ile Yoruba ni odun ibile ti se Pataki, idi niyi ti o fi je wipe awon esin ati ohun ti baba n la wa n bo ko ni iye.
Igbagbo awa Yoruba ni wipe Olorun kan soso ni o wa ati pe Olorun naa si tobi ju gbogbo awon orisa ibile ti o ku lo, Olorun yii ni Yoruba pe ni Olodumare ti won gba pe o n lo n sakoso aye ati orun.
Okanojokan onimo isaaju bii Olu Daramola (1975), Adebayo Jeje (1970) Ogunbowale P.O (1974) ni won ti salaye daaye kan nipa odun ibile Yoruba.
Alaaye ti a kan fe se nibi, ko ju lati kin ero won leyin, loju awon onimo yii won gba pe baba ni Olodumare je si gbogbo awon orisa ibile ti o ku, awon orisa wonyii ni iko ti a maa n ran si Olodumare, orisirisi ni awon orisa wonyii.
Awon kan duro gege bi oguna gbongbo ti o je wipe orun ni won ti wa si Aye iru won bee ni Obatala, Orunmila, Esu, Ogun ati beebee lo.
OBATALA: Itan so fun wa wipe Obatala ni Olodumare koko da ninu gbogbo orisa ati wipe Olodumare fun ni agbara lati maa ran ohun lowo nipa sise oju imu enu ati gbogbo awon eya ara ti o ku leyin ti Olodumare ba ti mo ara ni borogidi tan idi ni eyi ti a fi maa pee ni igbakeji Olodumare, ohun ni o maa je ki a maa kii bayii pe.
                             Obatala oninu funfun
                             Eni soju semu Orisa ni
                             Maa sin o …………...
Siwaju si a kole menu ba gbogbo orisa ti o ku ti o si ti di orisa akunlebo.
Itan si tun so fun w ape awon alagbara kan wa ti won ti n gbe ile aye yii rii sugbon ti won ti di orisa leyin iku won ti won n bo gege bi orisa lati fi emi imoore ati idunu won han si won ni iranti oore ti won ti se nigba aye won.  Iru awon orisi wonyii ni oke – Ibadan ni ilu Ibadan, Olosunta ni ilu Ikere – Ekiti, Agolomologo ni odo Ikare Akoko ati ni Idanre naa won maa n bo Orosun fun abo ti o peye ni igba ogun.
Looto, gbogbo ile Yoruba ni a ti n se odun ogun sibe o se Pataki o si tun gbile jule ninu awon odun ibile ni ilu Ire – Ekiti, Ado – Ekiti, Ondo ati Ilesa.
A ko si ni saifi enu ba odun egungun nitoripe gbogbo ile Yoruba ni a ti n see, igbagbo won si ni wipe awon baba n la wa ti o ti ku ni o pada waye ninu ago to won si fe dara po mo wa lati le se ibeere fun awon ohun ti a ba fe lowo won.
Lakootan awon odun wonyii ni o ni aworo Pataki ise won aworo si ni lati se agbateru ni ojo odun naa, oba ni o si maa n je olori awon Aworo odun ibile ni ile Yoruba.
AIGBAGBO AWON YORUBA NIPA BIBO AWON ORISA WONYII
Igbagbo awon Yoruba nipa bibo awon orisa wonyii ni wipe ti won ba ti boa won orisa naa, gbogbo ire odun naa, yoo je tiwon, Aboyun ile a bi were, Agan ti ko bi a towo ala bosun ati wipe ibikibi ko ni wo ile to won wa.  Won sit un ni igbagbo wipe odun kan ti won ba fi awon orisa wonyii sile laibo odun naa ko ni dun fun won.  Ile koni roju oko ko ni raye, orisirisi ajalu ni o maa de si ara ilu nitori pea won orisa wonyii le bi nu si won, ti orisa ba si binu ayafi ti won ba bi Ifa leere ohun ti won yoo fi petu si okan orisa bee lati da isele ibi duro laarin ilu.  Idi ni eyi ti awon Yoruba fi ni igbagbo ti o muna doko lori awon orisa ibile won gbogbo.

ITAN ISEDALE ILU IKARE AKOKO
Opo itan ni a gbo wipe o room Yoruba ti se tedo si ile Ife di oni olooni, bee naa ni itan ilu Ikare se pin si ona meji.
Itan ti a gbo lati enu Kabiyesi Owa Ale ti ilu Ikare Akoko ni ojo keta osu karun – un odun 2008, so pe Agbaode ni oruko eni to koko te ilu Ikare do o si je okan lara awon omo Oduduwa, Agbaode, kuro ni Ife pelu ebii re ati opolopo eniyan ni Adugbo Eruwa, O kuro ni Ife nitori pe o yan Ade siwaju awon egbon ore, Agbaode ni o je Oba siwaju awon egbon re ni won se n pe ni Owa ti o le ti o tumo si OWA ALE, Owa ni ile Yoruba duro gege bii Oba, apeere ni Owa abokun, owa agbajo.
Ni eyin igba ti o ti rin kaakiri fun opo odun.  O dowo ni ibi apa oke n la kan ti a n pe ni oke Ikare ki o to di wipe o rewale asa, o ni oloye mejila bii Oniku, Olokoja, Onigbede, Aro, Olowa Balogun, Elemeje, Elekan, Onisakunle, Olokepaye, Eleketun, leyin eyi awon Owa Ale miran ti o tun je ni Rotoye, Olarun Ademoye, Diromoye Agbole, Amugbirigidi, Ameyinpa, Orukusuku, Adetiba, Ojugbo Gbogi, Owajimite iranja Ajiboye, Adegbite ati Kolapo Adedoyin ti o wa lori ite bayii.
Itan ti a gbo lati enu ogbeni Jimoh Ologun ni adugbo okoja ni ojo kerinlelogun osu karun – un ni odun 2008 bakanna so fun wa pe lati ilu Ife ni Ikare ti yapa wa ti won si tedo si ibi ti won wa di oni oloni.  Ajagunna ti o je okan lara awon omo oduduwa ni o kuro ni ile Ife pelu opo eniyan.  Ibi ti won ti kuro Ife ni adugbo Ilare ti won si tedo si isale Ikare di oni oloni.
Leyin ti Olukare akoko eyi ti o n je Ajagunna yii roke alo waon Olukare miran ti o tun je ni Amusa Momoh, Hasan Babatunde, Ajogunna, Olonoola Elegbe Ketimigbo Ata alila Arokerese Oba Momoh Adu ati bee bee lo pelu Momoh Akadiri Saliu ti o wa lori oye bayii.
Awon ijoye Olukare ni oloye sasere olododo orisakumen, elekan, olokeruwa, obanla, omotosho Yeyemeso Iyaalaye Olodalyare Onigbede Balogun.


IPO OWA ALE ATI OLU IKARE
Awon wonyii ni o duro gege bii asiwaju fun awon eniyan ilu ikare Akoko, ni o maa n se odun ojo ikare, odun ojo ikare, odun Agolomolodo, imole okela o si tun je  oba olori elesin musulumi.
Owa Ale ni o maa se odun Aringiya, ijeroba, odun ijesu ti a mo si igbodo, gidigbe ijawene omolokoja Aoyo ati bee bee lo.
ISE ATI ESIN AWON ARA ILU NAA
Ise agbe ati ise onisowo ni ise, Pataki julo ti awon ara ilu ikare n se, won mo nipa ogbin koko , won tun maa n gbin isu koko , agbado ati nnkan ewe leyin eyi opolopo ise ni won sit un se gege bii ise aso hihun , Aro mimu, ise Agbede ati owo sise, awon omowe onise ijoba naa ko si lo un ka.
ESIN
Ni Aye atijo orisirisi orisa ni awon ara ilu yii n bo ki awon esin igbalode to daye lara awon orisa wonyii ni ifa, urere, osanyin, oya, Atan, Gayingayin ati bee bee lo . ko si eyi ti won fi owo yepere mu ninu awon orisa wonyii, karakara ni won si n se odun awon orisa naa ni sise-n-tele sugbon ni igba ti esin igbalode , imale ati igbagbo de, n se ni awon ara ilu lokunrin ati lobinrin tewo gba esin naa, eyi si mu ki esin ibile bere si kase nile titi di oni yii.
ITOSE ORO
1.                 Itan ti o romo owa Ale
2.                 Itan ti o romo olukare.
ORISUN IMO
1.                 Lati enu kabiyesi owa Ale ti ilu ikare- Akoko
2.                 Lati enu jimoh ologun ni Adgbo okoja ni ilu ikare- Akoko.
          Iwadii yii waye ni ojo keta osu karun-un odun 2008.

Reactions

You may like these posts